BannerFans.com

Tuesday, 19 December 2017

OLONGBO


Olongbo je abami eran to n gbe ile, awon agba je ki a mo pe ti enikan ba n sa'aare ninu ile ti olongbo ba ti nsa fun onitohun, iyen duro fun aridaju wipe aisan yen lo maa pa onitohun, sugbon ti olongbo ba ti n fara nu alaare, eyi tumo si wipe alaafia ma de sonitohun laipe.
   Olongbo kii sadede ya'gbe si ile lasan, o ma n gbe ile, ti yio ya igbe si, ti yio si da erupe bo.
     Ti olongbo ba fe gun (ibalopo), ako yio fo ori abo koja lasan won kii gun bi ti eran toku .
Enu ni olongbo ti nbimo tire, o le bi meji, meta tabi merin, ti o ba si fee bi omo, yio lo si ibi kolofin bii aarin-orule.
Olongbo ni oju inu to nlo,eyi lo faa ti a won agba se ma nya lo fun iranse won.
A le so wipe ode ni olongbo, nitori wipe won ma n fi de ile nitori ekute, sugbon apa-adele
ni koje kamope ode ni tori eran lo ma n je.
Oruko miran ti Yoruba npe olongbo ni "OLOGINNI"
Olongbo ni awo lorisirisi bi dudu, pupa resu-resu, funfun, ati bebe lo .

1 comment:

  1. Las Vegas Casino | DrmCD
    The 통영 출장샵 Las Vegas Strip is 여수 출장안마 full of gambling, casino, and 청주 출장마사지 sports. There's plenty of gaming and a plethora 대구광역 출장안마 of entertainment. You'll find a full menu 광양 출장마사지 of games

    ReplyDelete